O si ṣe lẹhin eyi, Absalomu si pèse kẹkẹ́ ati ẹṣin fun ara rẹ̀, ati adọta ọmọkunrin ti yio ma sare niwaju rẹ̀.
Absalomu si dide ni kutukutu, o si duro li apakan ọ̀na ẹnu ibode: o si ṣe, bi ẹnikan ba ni ẹjọ ti o nfẹ mu tọ̀ ọba wá fun idajọ, a si pè e sọdọ rẹ̀, a si bi i pe, Ara ilu wo ni iwọ? on a si dahùn pe, Iranṣẹ rẹ ti inu ọkan ninu ẹya Israeli wá.
Absalomu a si wi fun u pe Wõ, ọ̀ran rẹ sa dara, o si tọ: ṣugbọn ko si ẹnikan ti ọba fi aṣẹ fun lati yẹ ọ̀ran rẹ wò.
Absalomu a si wipe, A ba jẹ fi mi ṣe onidajọ ni ilẹ yi! ki olukuluku ẹniti o ni ẹjọ tabi ọ̀ran kan ba le ma tọ̀ mi wa, emi iba si ṣe idajọ otitọ fun u.
Bẹ̃ni bi ẹnikan ba si sunmọ ọ lati tẹriba fun u, on a si nawọ́ rẹ̀, a si dì i mu, a si fi ẹnu kò o li ẹnu.
Iru iwà bayi ni Absalomu a ma hù si gbogbo Israeli ti o tọ̀ ọba wá nitori idajọ: Absalomu si fa ọkàn awọn enia Israeli sọdọ rẹ̀.
O si ṣe lẹhin ogoji ọdun, Absalomu si wi fun ọba pe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi ki o lọ, ki emi o si san ileri mi ti emi ti ṣe fun Oluwa, ni Hebroni.
Nitori ti iranṣẹ rẹ ti jẹ'jẹ kan nigbati emi mbẹ ni Geṣuri ni Siria, pe, Bi Oluwa ba mu mi pada wá si Jerusalemu, nitotọ, emi o si sin Oluwa.
Ọba si wi fun u pe, Ma lọ li alafia. O si dide, o si lọ si Hebroni.
Ṣugbọn Absalomu rán amí sarin gbogbo ẹyà Israeli pe, Nigbati ẹnyin ba gbọ́ iró ipè, ki ẹnyin si wipe, Absalomu jọba ni Hebroni.
Igba ọkunrin si bá Absalomu ti Jerusalemu jade, ninu awọn ti a ti pè; nwọn si lọ ninu aimọ̀kan wọn, nwọn kò si mọ nkankan.
Absalomu si ranṣẹ pè Ahitofeli ara Giloni, igbimọ̀ Dafidi, lati ilu rẹ̀ wá, ani lati Gilo, nigbati o nrú ẹbọ. Idìtẹ̀ na si le; awọn enia si npọ̀ sọdọ Absalomu.
Ẹnikan si wá rò fun Dafidi pe, Ọkàn awọn ọkunrin Israeli ṣi si Absalomu.
Dafidi si wi fun gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ ti o wà lọdọ rẹ̀ ni Jerusalemu pe, Ẹ dide, ẹ jẹ ki a salọ, nitoripe kò si ẹniti yio gbà wa lọwọ Absalomu: ẹ yara, ki a lọ kuro, ki on má ba yara le wa ba, ki o má si mu ibi ba wa, ki o má si fi oju idà pa ilu run.
Awọn iranṣẹ ọba si wi fun ọba pe, Gẹgẹ bi gbogbo eyi ti oluwa wa ọba nfẹ, wõ, awa iranṣẹ rẹ ti mura.
Ọba si jade, gbogbo ile rẹ̀ si tẹle e. Ọba si fi mẹwa ninu awọn obinrin rẹ̀ silẹ lati ma ṣọ ile.
Ọba si jade, gbogbo enia si tẹle e, nwọn si duro ni ibikan ti o jina.
Gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ si kọja li ọtún li osì rẹ̀, ati gbogbo awọn Kereti, ati gbogbo awọn Peleti, ati gbogbo awọn Giti, ẹgbẹta ọmọkunrin ti ntọ̀ ọ lẹhin lati Gati wá, si kọja niwaju ọba.
Ọba si wi fun Ittai, ara Giti nì pe, Ẽṣe ti iwọ fi mba wa lọ pẹlu? pada, ki o si ba ọba joko: nitoripe alejo ni iwọ, iwọ si ti fi ilu rẹ silẹ.
Lana yi ni iwọ de, emi ha si le mu ki iwọ ma ba wa lọ kakiri loni bi? emi nlọ si ibikibi ti mo ba ri: pada, ki o si mu awọn arakunrin rẹ pada, ki ãnu ati otitọ ki o pẹlu rẹ.
Ittai si da ọba lohùn, o si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ lãye, ati bi oluwa mi ọba ti mbẹ lãye, nitotọ nibikibi ti oluwa mi ọba ba gbe wà, ibakàn ṣe ninu ikú, tabi ninu ìye, nibẹ pẹlu ni iranṣẹ rẹ yio gbe wà.
Dafidi si wi fun Ittai pe, Lọ ki o si rekọja. Ittai ará Giti nì si rekọja, ati gbogbo awọn ọmọkunrin rẹ̀, ati gbogbo awọn ọmọ kekeke ti o wà lọdọ rẹ̀.
Gbogbo ilu na si fi ohùn rara sọkun, gbogbo enia si rekọja; ọba si rekọja odo Kidroni, gbogbo awọn enia na si rekọja, si ihà ọ̀na iju.
Si wõ, Sadoku pẹlu ati gbogbo awọn ọmọ Lefi ti o wà lọdọ rẹ̀ si nru apoti-ẹri Ọlọrun: nwọn si gbe apoti-ẹri Ọlọrun na kalẹ; Abiatari si goke, titi gbogbo awọn enia si fi dẹkun ati ma kọja lati ilu wá.
Ọba si wi fun Sadoku pe, Si tun gbe apoti-ẹri Ọlọrun na pada si ilu: bi emi ba ri oju rere gbà lọdọ Oluwa, yio si tun mu mi pada wá, yio si fi apoti-ẹri na hàn mi ati ibugbe rẹ̀.
Ṣugbọn bi on ba si wi pe, Emi kò ni inu didùn si ọ; wõ, emi niyi, jẹ ki on ki o ṣe si mi gẹgẹ bi o ti tọ́ li oju rẹ̀.
Ọba si wi fun Sadoku alufa pe, Iwọ kọ́ ariran? pada si ilu li alafia, ati awọn ọmọ rẹ mejeji pẹlu rẹ, Ahimaasi ọmọ rẹ, ati Jonatani ọmọ Abiatari.
Wõ, emi o duro ni pẹtẹlẹ iju nì, titi ọ̀rọ o fi ti ọdọ rẹ wá lati sọ fun mi.
Sadoku ati Abiatari si gbe apoti-ẹri Ọlọrun pada si Jerusalemu: nwọn si gbe ibẹ̀.
Dafidi si ngoke lọ ni oke Igi ororo, o si nsọkun bi on ti ngoke lọ, o si bò ori rẹ̀, o nlọ laini bata li ẹsẹ: gbogbo enia ti o wà lọdọ rẹ̀, olukuluku ọkunrin si bò ori rẹ̀, nwọn si ngoke, nwọn si nsọkun bi nwọn ti ngoke lọ.
Ẹnikan si sọ fun Dafidi pe, Ahitofeli wà ninu awọn ọlọ̀tẹ̀ Absalomu. Dafidi si wipe, Oluwa, emi bẹ̀ ọ, sọ ìmọ Ahitofeli di asan.
O si ṣe, Dafidi de ori oke, nibiti o gbe wolẹ̀ sin Ọlọrun, si wõ, Huṣai ara Arki nì si wá lati pade rẹ̀ ti on ti aṣọ rẹ̀ yiya, ati erupẹ, li ori rẹ̀.
Dafidi si wi fun u pe, bi iwọ ba bá mi kọja, iwọ o si jẹ idiwọ fun mi.
Bi iwọ ba si pada si ilu, ti o si wi fun Absalomu pe, Emi o ṣe iranṣẹ rẹ, ọba, gẹgẹ bi emi ti ṣe iranṣẹ baba rẹ nigba atijọ, bẹ̃li emi o si jẹ iranṣẹ rẹ nisisiyi: ki iwọ ki o si bà ìmọ Ahitofeli jẹ.
Ṣe Sadoku ati Abiatari awọn alufa wà nibẹ pẹlu rẹ? yio si ṣe, ohunkohun ti iwọ ba gbọ́ lati ile ọba wá, iwọ o si sọ fun Sadoku ati Abiatari awọn alufa.
Wõ, nwọn si ni ọmọ wọn mejeji nibẹ pẹlu wọn, Ahimaasi ọmọ Sadoku, ati Jonatani ọmọ Abiatari; lati ọwọ́ wọn li ẹnyin o si rán ohunkohun ti ẹnyin ba gbọ́ si mi.
Huṣai ọrẹ Dafidi si wá si ilu, Absalomu si wá si Jerusalemu.