O si ṣe, lẹhin eyi, Absalomu ọmọ Dafidi ni aburo obinrin kan ti o ṣe arẹwà, orukọ rẹ̀ a si ma jẹ́ Tamari; Amnoni ọmọ Dafidi si fẹràn rẹ̀.
Amnoni si banujẹ titi o fi ṣe aisan nitori Tamari aburo rẹ̀ obinrin; nitoripe wundia ni; o si ṣe ohun ti o ṣoro li oju Amnoni lati ba a ṣe nkan kan.
Ṣugbọn Amnoni ni ọrẹ́ kan, orukọ rẹ̀ a si ma jẹ Jonadabu, ọmọ Ṣimea ẹgbọ́n Dafidi: Jonadabu si jẹ alarekereke enia gidigidi.
O si wi fun u pe, ẽṣe ti iwọ ọmọ ọba nfi nrù lojojumọ bayi? o kì yio ha sọ fun mi? Amnoni si wi fun u pe, emi fẹ Tamari aburo Absalomu arakunrin mi.
Jonadabu si wi fun u pe, dubulẹ ni ibusùn rẹ ki iwọ ki o si ṣe bi ẹnipe ara rẹ kò yá: baba rẹ yio si wá iwò ọ, iwọ o si wi fun u pe, Jọ̀wọ jẹ ki Tamari aburo mi ki o wá ki o si fun mi li onjẹ ki o si se onjẹ na niwaju mi ki emi ki o ri i, emi o si jẹ ẹ li ọwọ́ rẹ̀.
Amnoni si dubulẹ, o si ṣe bi ẹnipe on ṣaisan: ọba si wá iwò o, Amnoni si wi fun ọba pe, Jọwọ, jẹ ki Tamari aburo mi ki o wá, ki o si din akarà meji li oju mi, emi o si jẹ li ọwọ́ rẹ̀.
Dafidi si ranṣẹ si Tamari ni ile pe, Lọ si ile Amnoni ẹgbọ́n rẹ, ki o si ṣe ti onjẹ fun u.
Tamari si lọ si ile Amnoni ẹgbọ́n rẹ̀, on si mbẹ ni ibulẹ. Tamari si mu iyẹfun, o si pò o, o si fi ṣe akara li oju rẹ̀, o si din akara na.
On si mu awo na, o si dà a sinu awo miran niwaju rẹ̀; ṣugbọn o kọ̀ lati jẹ. Amnoni si wipe, jẹ ki gbogbo ọkunrin jade kuro lọdọ mi. Nwọn si jade olukuluku ọkunrin kuro lọdọ rẹ̀.
Amnoni si wi fun Tamari pe, mu onjẹ na wá si yara, emi o si jẹ lọwọ rẹ. Tamari si mu akara ti o ṣe, o si mu u tọ̀ Amnoni ẹgbọ́n rẹ̀ ni iyẹwu.
Nigbati o si sunmọ ọ lati fi onjẹ fun u, on si di i mu, o si wi fun u pe, wá dubulẹ tì mi, aburo mi.
On si da a lohùn wipe, Bẹ̃kọ ẹgbọ́n mi, máṣe tẹ́ mi; nitoripe ko tọ́ ki a ṣe iru nkan bẹ̃ ni Israeli, iwọ máṣe huwa were yi.
Ati emi, nibo li emi o gbe itiju mi wọ̀? iwọ o si dabi ọkan ninu awọn aṣiwere ni Israeli. Njẹ nitorina, emi bẹ̀ ọ, sọ fun ọba; nitoripe on kì yio kọ̀ lati fi mi fun ọ.
Ṣugbọn o kọ̀ lati gbọ́ ohùn rẹ̀; o si fi agbara mu u, o si ṣẹgun rẹ̀, o si ba a dapọ̀.
Amnoni si korira rẹ̀ gidigidi, irira na si wá jù ifẹ ti on ti ni si i ri lọ. Amnoni si wi fun u pe, Dide, ki o si ma lọ.
On si wi fun u pe, Ko ha ni idi bi; lilé ti iwọ nlé mi yi buru jù eyi ti iwọ ti ṣe si mi lọ. Ṣugbọn on ko fẹ gbọ́ tirẹ̀.
On si pe ọmọ-ọdọ rẹ̀ ti iṣe iranṣẹ rẹ̀, o si wi fun u pe, Jọwọ, tì obinrin yi sode fun mi, ki o si ti ilẹkùn mọ ọ.
On si ni aṣọ alaràbara kan li ara rẹ̀: nitori iru aṣọ awọ̀leke bẹ̃ li awọn ọmọbinrin ọba ti iṣe wundia ima wọ̀. Iranṣẹ rẹ̀ si mu u jade, o si ti ilẹkun mọ ọ.
Tamari si bu ẽru si ori rẹ̀, o si fa aṣọ alaràbara ti mbẹ lara rẹ̀ ya, o si ka ọwọ́ rẹ̀ le ori, o si nkigbe bi o ti nlọ.
Absalomu ẹgbọ́n rẹ̀ si bi i lere pe, Amnoni ẹgbọ́n rẹ ba ọ ṣe bi? njẹ aburo mi, dakẹ; ẹgbọ́n rẹ ni iṣe; má fi nkan yi si ọkàn rẹ. Tamari si joko ni ibanujẹ ni ile Absalomu ẹgbọ́n rẹ̀.