II. Sam 12:22-23

II. Sam 12:22-23 YBCV

O si wipe, nigbati ọmọ na mbẹ lãye, emi gbawẹ, emi si sọkun: nitoriti emi wipe, Tali o mọ̀ bi Ọlọrun o ṣãnu mi, ki ọmọ na ki o le yè. Ṣugbọn nisisiyi o ti kú, nitori kili emi o ṣe ma gbawẹ? emi le mu u pada wá mọ bi? emi ni yio tọ̀ ọ lọ, on ki yio si tun tọ̀ mi wá.