II. Sam 12:18-24

II. Sam 12:18-24 YBCV

O si ṣe, ni ijọ keje, ọmọ na si kú. Awọn iranṣẹ Dafidi si bẹ̀ru lati wi fun u pe, ọmọ na kú: nitori ti nwọn wipe, Kiye si i, nigbati ọmọ na mbẹ lãye, awa sọ̀rọ fun u, on kò si gbọ́ ohùn wa: njẹ yio ti ṣẹ́ ara rẹ̀ ni iṣẹ́ to, bi awa ba wi fun u pe, ọmọ na kú? Nigbati Dafidi si ri pe awọn iranṣẹ rẹ̀ nsọ̀rọ kẹlẹkẹlẹ, Dafidi si kiye si i pe ọmọ na kú: Dafidi si bere lọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ọmọ na kú bi? nwọn si da a li ohùn pe, O kú. Dafidi si dide ni ilẹ, o si wẹ̀, o fi ororo pa ara, o si parọ̀ aṣọ rẹ̀, o si wọ inu ile Oluwa lọ, o si wolẹ sìn: o si wá si ile rẹ̀ o si bere, nwọn si gbe onjẹ kalẹ niwaju rẹ̀, o si jẹun. Awọn iranṣẹ rẹ̀ si bi li ere pe, Ki li eyi ti iwọ ṣe yi? nitori ọmọ na nigbati o mbẹ lãye iwọ gbawẹ, o si sọkun; ṣugbọn nigbati ọmọ na kú, o dide o si jẹun. O si wipe, nigbati ọmọ na mbẹ lãye, emi gbawẹ, emi si sọkun: nitoriti emi wipe, Tali o mọ̀ bi Ọlọrun o ṣãnu mi, ki ọmọ na ki o le yè. Ṣugbọn nisisiyi o ti kú, nitori kili emi o ṣe ma gbawẹ? emi le mu u pada wá mọ bi? emi ni yio tọ̀ ọ lọ, on ki yio si tun tọ̀ mi wá. Dafidi si ṣipẹ fun Batṣeba aya rẹ̀, o si wọle tọ̀ ọ, o si ba a dapọ̀: on si bi ọmọkunrin kan, Dafidi si sọ orukọ rẹ̀ ni Solomoni: Oluwa si fẹ ẹ.