II. Sam 12:18-19

II. Sam 12:18-19 YBCV

O si ṣe, ni ijọ keje, ọmọ na si kú. Awọn iranṣẹ Dafidi si bẹ̀ru lati wi fun u pe, ọmọ na kú: nitori ti nwọn wipe, Kiye si i, nigbati ọmọ na mbẹ lãye, awa sọ̀rọ fun u, on kò si gbọ́ ohùn wa: njẹ yio ti ṣẹ́ ara rẹ̀ ni iṣẹ́ to, bi awa ba wi fun u pe, ọmọ na kú? Nigbati Dafidi si ri pe awọn iranṣẹ rẹ̀ nsọ̀rọ kẹlẹkẹlẹ, Dafidi si kiye si i pe ọmọ na kú: Dafidi si bere lọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ọmọ na kú bi? nwọn si da a li ohùn pe, O kú.