II. Sam 12:1-7

II. Sam 12:1-7 YBCV

OLUWA si ran Natani si Dafidi. On si tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Ọkunrin meji mbẹ ni ilu kan; ọkan jẹ ọlọrọ̀, ekeji si jẹ talaka. Ọkunrin ọlọrọ̀ na si ni agutan ati malu li ọ̀pọlọpọ, Ṣugbọn ọkunrin talaka na kò si ni nkan, bikoṣe agutan kekere kan, eyi ti o ti rà ti o si ntọ́: o si dagba li ọwọ́ rẹ̀ pẹlu awọn ọmọ rẹ̀; a ma jẹ ninu onjẹ rẹ̀, a si ma mu ninu ago rẹ̀, a si ma dubulẹ li aiya rẹ̀, o si dabi ọmọbinrin kan fun u. Alejo kan si tọ̀ ọkunrin ọlọrọ̀ na wá, on kò si fẹ mu ninu agutàn rẹ̀, ati ninu malu rẹ̀, lati fi ṣe alejo fun ẹni ti o tọ̀ ọ wá: o si mu agutan ọkunrin talaka na fi ṣe alejo fun ọkunrin ti o tọ̀ ọ wá. Ibinu Dafidi si fàru gidigidi si ọkunrin na; o si wi fun Natani pe, Bi Oluwa ti mbẹ lãye, ọkunrin na ti o ṣe nkan yi, kikú ni yio kú. On o si san agutan na pada ni ìlọ́po mẹrin, nitoriti o ṣe nkan yi, ati nitoriti kò ni ãnu. Natani si wi fun Dafidi pe, Iwọ li ọkunrin na. Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, Emi fi ọ jọba lori Israeli, emi si gbà ọ lọwọ Saulu