O si ṣe, ni igbà aṣalẹ kan, Dafidi si dide ni ibusùn rẹ̀, o si nrìn lori orule ile ọba, lati ori orule na li o si ri obinrin kan ti o nwẹ̀ ara rẹ̀; obinrin na si ṣe arẹwa jọjọ lati wò.
Dafidi si ranṣẹ, o si bere obinrin na. Ẹnikan si wipe, Eyi kọ Batṣeba, ọmọbinrin Eliami, aya Uria ará Hitti?
Dafidi si rán awọn iranṣẹ, o si mu u; on si wọ inu ile tọ̀ ọ lọ, on si ba a dapọ̀: nigbati o si wẹ ara rẹ̀ mọ́ tan, o si pada lọ si ile rẹ̀.
Obinrin na si fẹra kù, o si ranṣẹ o si sọ fun Dafidi, o si wipe, Emi fẹra kù.
Dafidi si ranṣẹ si Joabu, pe, Ran Uria ará Hitti si mi. Joabu si ran Uria si Dafidi.
Nigbati Uria si de ọdọ rẹ̀, Dafidi si bi i li ere alafia Joabu, ati alafia awọn enia na, ati bi ogun na ti nṣe.
Dafidi si wi fun Uria pe, Sọkalẹ lọ si ile rẹ, ki o si wẹ ẹsẹ rẹ. Uria si jade kuro ni ile ọba, onjẹ lati ọdọ ọba wá si tọ̀ ọ lẹhin.
Ṣugbọn Uria sùn li ẹnu-ọ̀na ile ọba lọdọ gbogbo iranṣẹ oluwa rẹ̀, kò si sọkalẹ lọ si ile rẹ̀.
Nigbati nwọn si sọ fun Dafidi pe, Uria kò sọkalẹ lọ si ile rẹ̀, Dafidi si wi fun Uria pe, Ṣe ọ̀na àjo ni iwọ ti wá? eha ti ṣe ti iwọ kò fi sọkalẹ lọ si ile rẹ?
Uria si wi fun Dafidi pe, Apoti-ẹri, ati Israeli, ati Juda joko ninu agọ; ati Joabu oluwa mi, ati awọn iranṣẹ oluwa mi wà ni ibudo ni pápa: emi o ha lọ si ile mi, lati jẹ ati lati mu, ati lati ba obinrin mi sùn? bi iwọ ba wà lãye, ati bi ẹmi rẹ si ti mbẹ lãye, emi kì yio ṣe nkan yi.
Dafidi si wi fun Uria pe, Si duro nihin loni, li ọla emi o si jẹ ki iwọ ki o lọ. Uria si duro ni Jerusalemu li ọjọ na, ati ijọ keji.
Dafidi si pè e, o si jẹ, o si mu niwaju rẹ̀; o si mu ki ọti ki o pa a: on si jade li alẹ lọ si ibusùn rẹ̀ lọdọ awọn iranṣẹ oluwa rẹ̀, kò si sọkalẹ lọ si ile rẹ̀.
O si ṣe li owurọ Dafidi si kọwe si Joabu, o fi rán Uria.
O si kọ sinu iwe pe, Fi Uria siwaju ibi tí ogun gbe le, ki ẹ si bó o silẹ, ki nwọn le kọ lù u, ki o si kú.
O si ṣe nigbati Joabu ṣe akiyesi ilu na, o si yàn Uria si ibi kan ni ibi ti on mọ̀ pe awọn alagbara ọkunrin mbẹ nibẹ.
Awọn ọkunrin ilu na si jade wá, nwọn si ba Joabu jà: diẹ si ṣubu ninu awọn enia na ninu awọn iranṣẹ Dafidi; Uria ará Hitti si kú pẹlu.