O si ṣe, lẹhin igbati ọdun yipo, li akoko igbati awọn ọba ima jade ogun, Dafidi si rán Joabu, ati awọn iranṣẹ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ati gbogbo Israeli; nwọn si pa awọn ọmọ Ammoni, nwọn si dó ti Rabba. Dafidi si joko ni Jerusalemu.
O si ṣe, ni igbà aṣalẹ kan, Dafidi si dide ni ibusùn rẹ̀, o si nrìn lori orule ile ọba, lati ori orule na li o si ri obinrin kan ti o nwẹ̀ ara rẹ̀; obinrin na si ṣe arẹwa jọjọ lati wò.
Dafidi si ranṣẹ, o si bere obinrin na. Ẹnikan si wipe, Eyi kọ Batṣeba, ọmọbinrin Eliami, aya Uria ará Hitti?
Dafidi si rán awọn iranṣẹ, o si mu u; on si wọ inu ile tọ̀ ọ lọ, on si ba a dapọ̀: nigbati o si wẹ ara rẹ̀ mọ́ tan, o si pada lọ si ile rẹ̀.
Obinrin na si fẹra kù, o si ranṣẹ o si sọ fun Dafidi, o si wipe, Emi fẹra kù.
Dafidi si ranṣẹ si Joabu, pe, Ran Uria ará Hitti si mi. Joabu si ran Uria si Dafidi.
Nigbati Uria si de ọdọ rẹ̀, Dafidi si bi i li ere alafia Joabu, ati alafia awọn enia na, ati bi ogun na ti nṣe.
Dafidi si wi fun Uria pe, Sọkalẹ lọ si ile rẹ, ki o si wẹ ẹsẹ rẹ. Uria si jade kuro ni ile ọba, onjẹ lati ọdọ ọba wá si tọ̀ ọ lẹhin.
Ṣugbọn Uria sùn li ẹnu-ọ̀na ile ọba lọdọ gbogbo iranṣẹ oluwa rẹ̀, kò si sọkalẹ lọ si ile rẹ̀.
Nigbati nwọn si sọ fun Dafidi pe, Uria kò sọkalẹ lọ si ile rẹ̀, Dafidi si wi fun Uria pe, Ṣe ọ̀na àjo ni iwọ ti wá? eha ti ṣe ti iwọ kò fi sọkalẹ lọ si ile rẹ?
Uria si wi fun Dafidi pe, Apoti-ẹri, ati Israeli, ati Juda joko ninu agọ; ati Joabu oluwa mi, ati awọn iranṣẹ oluwa mi wà ni ibudo ni pápa: emi o ha lọ si ile mi, lati jẹ ati lati mu, ati lati ba obinrin mi sùn? bi iwọ ba wà lãye, ati bi ẹmi rẹ si ti mbẹ lãye, emi kì yio ṣe nkan yi.