II. Sam 10:7-14

II. Sam 10:7-14 YBCV

Dafidi si gbọ́, o si rán Joabu, ati gbogbo ogun awọn ọkunrin alagbara. Awọn ọmọ Ammoni si jade, nwọn si tẹ́ ogun li ẹnu odi; ara Siria ti Soba, ati ti Rehobu, ati Iṣtobu, ati Maaka, nwọn si tẹ́ ogun ni papa fun ara wọn. Nigbati Joabu si ri i pe ogun na doju kọ on niwaju ati lẹhin, o si yàn ninu gbogbo awọn akikanju ọkunrin ni Israeli, o si tẹ́ ogun kọju si awọn ara Siria. O si fi awọn enia ti o kù le Abiṣai aburo rẹ̀ lọwọ, ki o le tẹ́ ogun kọju si awọn ọmọ Ammoni. O si wipe, Bi agbara awọn ara Siria ba si pọ̀ jù emi lọ, iwọ o si wá ràn mi lọwọ: ṣugbọn bi ọwọ́ awọn ọmọ Ammoni ba si pọ̀ jù ọ lọ, emi o si wá ràn ọ lọwọ. Mu ọkàn le, jẹ ki a ṣe onigboya nitori awọn enia wa, ati nitori awọn ilu Ọlọrun wa; Oluwa o si ṣe eyi ti o dara li oju rẹ̀. Joabu ati awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀ si ba awọn ara Siria pade ijà: nwọn si sa niwaju rẹ̀. Nigbati awọn ọmọ Ammoni si ri pe awọn ara Siria sá, awọn si sá niwaju Abiṣai, nwọn si wọ inu ilu lọ. Joabu si pada kuro lẹhin awọn ọmọ Ammoni, o si pada wá si Jerusalemu.