Awọn ọmọ Ammoni si ri pe, nwọn di ẹni irira niwaju Dafidi, awọn ọmọ Ammoni si ranṣẹ, nwọn si fi owo bẹ̀ ogun awọn ara Siria ti Betrehobu; ati Siria ti Soba, ẹgbãwa ẹlẹsẹ ati ti ọba Maaka, ẹgbẹrun ọkunrin, ati ti Iṣtobu ẹgbãfa ọkunrin.
Dafidi si gbọ́, o si rán Joabu, ati gbogbo ogun awọn ọkunrin alagbara.
Awọn ọmọ Ammoni si jade, nwọn si tẹ́ ogun li ẹnu odi; ara Siria ti Soba, ati ti Rehobu, ati Iṣtobu, ati Maaka, nwọn si tẹ́ ogun ni papa fun ara wọn.
Nigbati Joabu si ri i pe ogun na doju kọ on niwaju ati lẹhin, o si yàn ninu gbogbo awọn akikanju ọkunrin ni Israeli, o si tẹ́ ogun kọju si awọn ara Siria.
O si fi awọn enia ti o kù le Abiṣai aburo rẹ̀ lọwọ, ki o le tẹ́ ogun kọju si awọn ọmọ Ammoni.
O si wipe, Bi agbara awọn ara Siria ba si pọ̀ jù emi lọ, iwọ o si wá ràn mi lọwọ: ṣugbọn bi ọwọ́ awọn ọmọ Ammoni ba si pọ̀ jù ọ lọ, emi o si wá ràn ọ lọwọ.
Mu ọkàn le, jẹ ki a ṣe onigboya nitori awọn enia wa, ati nitori awọn ilu Ọlọrun wa; Oluwa o si ṣe eyi ti o dara li oju rẹ̀.
Joabu ati awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀ si ba awọn ara Siria pade ijà: nwọn si sa niwaju rẹ̀.
Nigbati awọn ọmọ Ammoni si ri pe awọn ara Siria sá, awọn si sá niwaju Abiṣai, nwọn si wọ inu ilu lọ. Joabu si pada kuro lẹhin awọn ọmọ Ammoni, o si pada wá si Jerusalemu.
Nigbati awọn ara Siria si ri pe nwọn di bibì ṣubu niwaju Israeli, nwọn si ko ara wọn jọ.
Hadareseri si ranṣẹ, o si mu awọn ara Siria ti o wà li oke odo jade wá: nwọn si wá si Helami; Ṣobaki olori ogun ti Hadareseri si ṣolori wọn.
Nigbati a sọ fun Dafidi, o si ko gbogbo Israeli jọ, nwọn si kọja Jordani, nwọn si wá si Helami. Awọn ara Siria si tẹ́ ogun kọju si Dafidi, nwọn si ba a jà.
Awọn ara Siria si sa niwaju Israeli; Dafidi si pa ninu awọn ara Siria ẽdẹgbẹrin awọn onikẹkẹ́, ati ọkẹ meji ẹlẹṣin, nwọn si kọlu Ṣobaki olori ogun wọn, o si kú nibẹ.
Nigbati gbogbo awọn ọba ti o wà labẹ Hadareseri si ri pe nwọn di bibì ṣubu niwaju Israeli, nwọn si ba Israeli lajà, nwọn si nsìn wọn. Awọn ara Siria si bẹ̀ru lati ràn awọn ọmọ Ammoni lọwọ mọ.