Ṣugbọn, olufẹ, ẹ máṣe gbagbe ohun kan yi, pe ọjọ kan lọdọ Oluwa bi ẹgbẹ̀run ọdún li o ri, ati ẹgbẹ̀run ọdún bi ọjọ kan. Oluwa kò fi ileri rẹ̀ jafara, bi awọn ẹlomiran ti ikà a si ijafara; ṣugbọn o nmu sũru fun nyin nitori kò fẹ ki ẹnikẹni ki o ṣegbé, bikoṣe ki gbogbo enia ki o wá si ironupiwada. Ṣugbọn ọjọ Oluwa mbọ̀wá bi olè li oru; ninu eyi ti awọn ọrun yio kọja lọ ti awọn ti ariwo nla, ati awọn imọlẹ oju ọrun yio si ti inu oru gbigbona gidigidi di yíyọ, aiye ati awọn iṣẹ ti o wà ninu rẹ̀ yio si jóna lulu. Njẹ bi gbogbo nkan wọnyi yio ti yọ́ nì, irú enia wo li ẹnyin iba jẹ ninu ìwa mimọ́ gbogbo ati ìwa-bi-Ọlọrun, Ki ẹ mã reti, ki ẹ si mã mura giri de díde ọjọ Ọlọrun, nitori eyiti awọn ọ̀run yio gbiná, ti nwọn yio di yíyọ́, ti awọn imọlẹ rẹ̀ yio si ti inu õru gbigbona gidigidi di yíyọ? Ṣugbọn gẹgẹ bi ileri rẹ̀, awa nreti awọn ọrun titun ati aiye titun, ninu eyiti ododo ngbé.
Kà II. Pet 3
Feti si II. Pet 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Pet 3:8-13
3 Awọn ọjọ
Ìwé Peteru kejì (2 Peter) yóò jẹ́ kí o nífẹ̀ẹ́ sí i láti dàgbà nínú ẹ̀mí, yóò jẹ́ kí o kọ ẹ̀kọ́ ẹ̀tàn, tí ìwọ yóò sì máà gbé ìgbé ayé ìwà mímọ́. Bí o ṣe ń retí bíbọ̀ Jesu, mọ̀ dájú pé Ọlọ́run ń pèsè gbogbo ohun tí o nílò láti gbé ìgbéayé ìwà bí Ọlọ́run.
7 Days
New Year. A New Day. God created these transitions to remind us that He is the God of New Beginnings. If God can speak the world into existence, He can certainly speak into the darkness of your life, creating for you a new beginning. Don’t you just love fresh starts! Just like this reading plan. Enjoy!
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò