Nitoripe bi Ọlọrun kò ba dá awọn angẹli si ti nwọn ṣẹ, ṣugbọn ti o sọ wọn si isalẹ ọrun apadi, ti o si fi wọn sinu ọgbun òkunkun biribiri awọn ti a pamọ́ de idajọ; Ti kò si dá aiye igbãni si, ṣugbọn o pa Noa pẹlu awọn meje miran mọ́, oniwasu ododo, nigbati o mu kikun omi wá sori aiye awọn alaiwà-bi-Ọlọrun; Ti o sọ awọn ilu Sodomu on Gomorra di ẽru, nigbati o fi ifọ́ afọbajẹ dá wọn lẹbi, ti o fi wọn ṣe apẹrẹ fun awọn ti yio jẹ alaiwà-bi-Ọlọrun; O si yọ Loti olõtọ, ẹniti ìwa wọbia awọn enia buburu bà ninu jẹ: (Nitori ọkunrin olõtọ nì bi o ti ngbe ãrin wọn, ti o nri, ti o si ngbọ́, lojojumọ ni ìwa buburu wọn mba ọkàn otitọ rẹ̀ jẹ́): Oluwa mọ̀ bi ã ti íyọ awọn ẹni ìwa-bi-Ọlọrun kuro ninu idanwo ati bi ã ti ípa awọn alaiṣõtọ ti a njẹ niya mọ dè ọjọ idajọ: Ṣugbọn pãpã awọn ti ntọ̀ ara lẹhin ninu ifẹkufẹ ẽri, ti nwọn si ngàn awọn ijoye, awọn ọ̀yájú, aṣe-tinuẹni, nwọn kò bẹ̀ru ati mã sọ̀rọ ẹgan si awọn oloye.
Kà II. Pet 2
Feti si II. Pet 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Pet 2:4-10
3 Awọn ọjọ
Ìwé Peteru kejì (2 Peter) yóò jẹ́ kí o nífẹ̀ẹ́ sí i láti dàgbà nínú ẹ̀mí, yóò jẹ́ kí o kọ ẹ̀kọ́ ẹ̀tàn, tí ìwọ yóò sì máà gbé ìgbé ayé ìwà mímọ́. Bí o ṣe ń retí bíbọ̀ Jesu, mọ̀ dájú pé Ọlọ́run ń pèsè gbogbo ohun tí o nílò láti gbé ìgbéayé ìwà bí Ọlọ́run.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò