Nitorina, ará, ẹ tubọ mã ṣe aisimi lati sọ ìpe ati yiyàn nyin di dajudaju: nitori bi ẹnyin ba nṣe nkan wọnyi, ẹnyin kì yio kọsẹ lai. Nitori bayi li a ó pese fun nyin lọpọlọpọ lati wọ ijọba ainipẹkun ti Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kristi. Nitorina emi ó mã mura lati mã mu nkan wọnyi wá si iranti nyin nigbagbogbo bi ẹnyin tilẹ ti mọ̀ wọn, ti ẹsẹ nyin si mulẹ ninu otitọ ti ẹnyin ni. Emi si rò pe o yẹ, niwọn igbati emi ba mbẹ ninu agọ́ yi, lati mã fi iranti rú nyin soke; Bi emi ti mọ̀ pe, bibọ́ agọ́ mi yi silẹ kù si dẹdẹ, ani bi Oluwa wa Jesu Kristi ti fihàn mi.
Kà II. Pet 1
Feti si II. Pet 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Pet 1:10-14
3 Awọn ọjọ
Ìwé Peteru kejì (2 Peter) yóò jẹ́ kí o nífẹ̀ẹ́ sí i láti dàgbà nínú ẹ̀mí, yóò jẹ́ kí o kọ ẹ̀kọ́ ẹ̀tàn, tí ìwọ yóò sì máà gbé ìgbé ayé ìwà mímọ́. Bí o ṣe ń retí bíbọ̀ Jesu, mọ̀ dájú pé Ọlọ́run ń pèsè gbogbo ohun tí o nílò láti gbé ìgbéayé ìwà bí Ọlọ́run.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò