II. A. Ọba 8:20-22

II. A. Ọba 8:20-22 YBCV

Li ọjọ rẹ̀ ni Edomu ṣọ̀tẹ kuro li abẹ ọwọ Juda, nwọn si jẹ ọba fun ara wọn. Bẹ̃ni Joramu rekọja siha Sairi, ati gbogbo awọn kẹkẹ́ pẹlu rẹ̀: o si dide li oru, o si kọlù awọn ara Edomu ti o yi i ka: ati awọn olori awọn kẹkẹ́: awọn enia si sá wọ inu agọ wọn. Bẹ̃ni Edomu ṣọ̀tẹ kuro labẹ ọwọ Juda titi o fi di oni yi. Nigbana ni Libna ṣọ̀tẹ li akokò kanna.