ELIṢA si wi fun obinrin na, ọmọ ẹniti o ti sọ di ãyè, wipe, Dide, si lọ, iwọ ati ile rẹ, ki o si ṣe atipo nibikibi ti iwọ ba le ṣe atipo: nitoriti Oluwa pe ìyan: yio si mu pẹlu ni ilẹ, li ọdun meje. Obinrin na si dide, o si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ enia Ọlọrun na: on si lọ pẹlu ile rẹ̀, nwọn si ṣe atipo ni ilẹ awọn ara Filistia li ọdun meje. O si ṣe lẹhin ọdun meje, ni obinrin na pada bọ̀ lati ilẹ awọn ara Filistia: on si jade lọ lati kepè ọba nitori ile rẹ̀ ati nitori ilẹ rẹ̀. Ọba si mba Gehasi iranṣẹ enia Ọlọrun na sọ̀rọ, wipe, Mo bẹ̀ ọ, sọ gbogbo ohun nla, ti Eliṣa ti ṣe fun mi. O si ṣe bi o ti nrò fun ọba bi o ti sọ okú kan di ãyè, si kiyesi i, obinrin na, ẹniti a sọ ọmọ rẹ̀ di ãyè kepè ọba nitori ilẹ rẹ ati nitori ile rẹ̀. Gehasi si wipe, Oluwa mi, ọba, eyi li obinrin na, eyi si li ọmọ rẹ̀ ti Eliṣa sọ di ãyè. Nigbati ọba si bère lọwọ obinrin na, o rohin fun u. Ọba si yàn iwẹ̀fa kan fun u, wipe, Mu ohun gbogbo ti iṣe ti rẹ̀ pada fun u, ati gbogbo erè oko lati ọjọ ti o ti fi ilẹ silẹ titi di isisiyi.
Kà II. A. Ọba 8
Feti si II. A. Ọba 8
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. A. Ọba 8:1-6
13 Days
Elisha is one of the most fascinating people found in God’s word. He was a prophet whose faith and miracles seem almost ridiculous. During this 13-day reading plan you will read through the life of Elisha and learn from his example of what life can look like when you let go and decide to live with ridiculous faith.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò