II. A. Ọba 6:18-20

II. A. Ọba 6:18-20 YBCV

Nigbati nwọn si sọ̀kalẹ tọ̀ ọ wá, Eliṣa gbadura si Oluwa, o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, bù ifọju lù awọn enia yi. On si bù ifọju lù wọn gẹgẹ bi ọ̀rọ Eliṣa. Eliṣa si wi fun wọn pe, Eyi kì iṣe ọ̀na, bẹ̃ni eyi kì iṣe ilu na: ẹ ma tọ̀ mi lẹhin, emi o si mu nyin wá ọdọ ọkunrin ti ẹnyin nwá. O si ṣe amọ̀na wọn lọ si Samaria. O si ṣe, nigbati nwọn de Samaria ni Eliṣa wipe, Oluwa la oju awọn enia wọnyi, ki nwọn ki o lè riran. Oluwa si là oju wọn; nwọn si riran; si kiyesi i, nwọn mbẹ li ãrin Samaria.