Ati li oṣù karun, li ọjọ keje oṣù, ti iṣe ọdun ikọkandilogun Nebukadnessari ọba, ọba Babeli, ni Nebusaradani olori ẹ̀ṣọ, iranṣẹ ọba Babeli, wá si Jerusalemu: O si fi ile Oluwa joná, ati ile ọba, ati gbogbo ile Jerusalemu, ati gbogbo ile enia nla li o fi iná sun. Gbogbo ogun awọn ara Kaldea ti o wà lọdọ olori ẹ̀ṣọ, si wó odi Jerusalemu palẹ yika kiri. Ati iyokù awọn enia ti o kù ni ilu ati awọn isansa ti o ya tọ̀ ọba, Babeli lọ, pẹlu ọ̀pọlọpọ enia ti o kù, ni Nebusaradani olori ẹ̀ṣọ kó lọ.
Kà II. A. Ọba 25
Feti si II. A. Ọba 25
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. A. Ọba 25:8-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò