O si ṣe li ọdun kẹtadilogoji igbèkun Jehoiakini ọba Juda, li oṣù kejila, li ọjọ kẹtadilọgbọn oṣù, Efil-merodaki ọba Babeli, li ọdun ti o bẹ̀rẹ si ijọba, o gbé ori Jehoiakini ọba Juda soke kuro ninu tubu; O si sọ̀rọ rere fun u, o si gbé ìtẹ rẹ̀ ga jù ìtẹ awọn ọba ti o wà pẹlu rẹ̀ ni Babeli. O si pàrọ awọn aṣọ tubu rẹ̀: o si njẹun nigbagbogbo niwaju rẹ̀ ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀. Ati ipin onjẹ tirẹ̀, jẹ ipin onjẹ ti ọba nfi fun u nigbagbogbo, iye kan li ojojumọ, ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀.
Kà II. A. Ọba 25
Feti si II. A. Ọba 25
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. A. Ọba 25:27-30
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò