II. A. Ọba 2:12-14

II. A. Ọba 2:12-14 YBCV

Eliṣa si ri i, o si kigbe pe, Baba mi, baba mi! kẹkẹ́ Israeli, ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀. On kò si ri i mọ: o si di aṣọ ara rẹ̀ mu, o si fà wọn ya si meji. On si mu agbáda Elijah ti o bọ́ lọwọ rẹ̀, o si pada sẹhin, o si duro ni bèbe Jordani. On si mu agbáda Elijah ti o bọ́ lọwọ rẹ̀, o si lù omi na, o si wipe, Nibo ni Oluwa Ọlọrun Elijah wà? Nigbati on pẹlu si lù omi na, nwọn si pinyà sihin ati sọhun: Eliṣa si rekọja.