II. A. Ọba 19:5-7

II. A. Ọba 19:5-7 YBCV

Bẹ̃li awọn iranṣẹ Hesekiah ọba wá sọdọ Isaiah. Isaiah si wi fun wọn pe, Bayi ni ki ẹ sọ fun oluwa nyin, Bayi li Oluwa wi pe, Máṣe bẹ̀ru ọ̀rọ wọnni, ti o ti gbọ́, ti awọn iranṣẹ ọba Assiria fi sọ ọ̀rọ odi si mi. Kiyesi i, emi o rán ẽmi kan si i, on o si gbọ́ ariwo, yio si pada si ilẹ on tikalarẹ̀; emi o si mu u ti ipa idà ṣubu ni ilẹ on tikalarẹ̀.