II. A. Ọba 18:5-7

II. A. Ọba 18:5-7 YBCV

O gbẹkẹle Oluwa Ọlọrun Israeli; ati lẹhin rẹ̀ kò si ẹniti o dabi rẹ̀ ninu gbogbo awọn ọba Juda, bẹ̃ni ṣãju rẹ̀ kò si ẹnikan. Nitoriti o faramọ Oluwa, kò si lọ kuro lẹhin rẹ̀, ṣugbọn o pa ofin rẹ̀ wọnni mọ, ti Oluwa ti pa li aṣẹ fun Mose. Oluwa si wà pẹlu rẹ̀; o si ṣe rere nibikibi ti o ba jade lọ: o si ṣọ̀tẹ si ọba Assiria, kò si sìn i mọ.