II. A. Ọba 15:27-28

II. A. Ọba 15:27-28 YBCV

Li ọdun kejilelãdọta Asariah ọba Juda ni Peka ọmọ Remaliah bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Samaria, o si jọba li ogun ọdun. O si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa: on kò lọ kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀.