LI ọdun kẹtadilọgbọ̀n Jeroboamu ọba Israeli ni Asariah (Ussiah) ọmọ Amasiah ọba Juda bẹ̀rẹ si ijọba. Ẹni ọdun mẹrindilogun li on iṣe nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mejilelãdọta ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ a ma jẹ Jekoliah ti Jerusalemu. O si ṣe eyiti o tọ loju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti baba rẹ̀ Amasiah ti ṣe; Kiki ibi giga wọnni ni a kò mu kuro: awọn enia nrubọ, nwọn si nsun turari sibẹ ni ibi giga wọnni.
Kà II. A. Ọba 15
Feti si II. A. Ọba 15
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. A. Ọba 15:1-4
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò