II. A. Ọba 14:28-29

II. A. Ọba 14:28-29 YBCV

Ati iyokù iṣe Jeroboamu ati gbogbo eyiti o ṣe, ati agbara rẹ̀, bi o ti jagun si, ati bi o ti gbà Damasku, ati Hamati, ti iṣe ti Juda, pada fun Israeli, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli? Jeroboamu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, ani, pẹlu awọn ọba Israeli; Sakariah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.