II. A. Ọba 14:23-25

II. A. Ọba 14:23-25 YBCV

Li ọdun kẹ̃dogun Amasiah ọmọ Joaṣi ọba Juda, Jeroboamu ọmọ Joaṣi ọba Israeli bẹ̀rẹ si ijọba ni Samaria, o si jọba li ọdun mọkanlelogoji. O si ṣe buburu li oju Oluwa: kò yà kuro ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀. O si tun mu agbègbe ilẹ Israeli pada lati atiwọ̀ Hamati titi de okun pẹ̀tẹlẹ, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa Ọlọrun Israeli, ti o ti sọ nipa ọwọ iranṣẹ rẹ̀ Jona woli, ọmọ Amittai, ti Gat-heferi.