LI ọdun kẹtalelogun Joaṣi ọmọ Ahasiah ọba Juda, Jehoahasi ọmọ Jehu bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Samaria. On si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, o si tẹ̀le ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀: on kò si lọ kuro ninu rẹ̀. Ibinu Oluwa si rú si Israeli, o si fi wọn le ọwọ Hasaeli ọba Siria, ati le ọwọ Benhadadi ọmọ Hasaeli, li ọjọ wọn gbogbo. Jehoahasi si bẹ̀ Oluwa, Oluwa si gbọ́ tirẹ̀; nitoriti o ri inira Israeli, nitoriti ọba Siria ni wọn lara. Oluwa si fun Israeli ni olugbala kan, bẹ̃ni nwọn si bọ́ lọwọ awọn ara Siria: awọn ọmọ Israeli si joko ninu agọ wọn bi ìgba atijọ.
Kà II. A. Ọba 13
Feti si II. A. Ọba 13
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. A. Ọba 13:1-5
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò