Nitori ẹlẹtàn pupọ̀ ti jade wá sinu aiye, awọn ti kò jẹwọ pe Jesu Kristi wá ninu ara. Eyi li ẹlẹtàn ati Aṣodisi Kristi. Ẹ kiyesara nyin, ki ẹ má sọ iṣẹ ti awa ti ṣe nù, ṣugbọn ki ẹnyin ki o ri ère kíkún gbà. Olukuluku ẹniti o ba nru ofin ti kò si duro ninu ẹkọ́ Kristi, kò gba Ọlọrun. Ẹniti o ba duro ninu ẹkọ́, on li o gbà ati Baba ati Ọmọ. Bi ẹnikẹni bá tọ̀ nyin wá, ti kò si mu ẹkọ́ yi wá, ẹ máṣe gbà a si ile, ki ẹ má si ṣe kí i. Nitori ẹniti o ba ki i, o ni ọwọ́ ninu iṣẹ buburu rẹ̀. Bi mo ti ni ohun pupọ̀ lati kọwe si nyin, emi kò fẹ lo tákàdá ati tàdãwa. Ṣugbọn emi ni ireti lati tọ nyin wá ati lati ba nyin sọrọ lojukoju, ki ayọ̀ nyin ki o le kún. Awọn ọmọ arabinrin rẹ ayanfẹ ki ọ. Amin.
Kà II. Joh 1
Feti si II. Joh 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Joh 1:7-13
2 Weeks
Jesus Himself said anyone who loves Him will obey His teaching. No matter what it costs us personally, our obedience matters to God. The "Obedience" reading plan walks through what the Scriptures say about obedience: How to maintain a mindset of integrity, the role of mercy, how obeying frees us and blesses our lives, and more.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò