II. Joh 1:1-2

II. Joh 1:1-2 YBCV

EMI alàgba si ayanfẹ obinrin ọlọlá ati awọn ọmọ rẹ̀, awọn ti mo fẹ li otitọ; kì si iṣe emi nikan, ṣugbọn gbogbo awọn ti o mọ̀ otitọ pẹlu; Nitori otitọ ti ngbé inu wa, yio si mã ba wa gbé titi.