NITORI nipa ti ipinfunni fun awọn enia mimọ́, kò ni pe mo nkọwe si nyin ju bẹ̃ lọ. Nitori mo mọ̀ imura-tẹlẹ nyin, eyiti mo fi yangàn fun awọn ara Makedonia nitori nyin, pe, Akaia ti mura tan niwọn ọdún kan ti o kọja; itara nyin si ti rú ọ̀pọlọpọ soke. Ṣugbọn mo ti rán awọn arakunrin, ki iṣogo wa nitori nyin ki o máṣe jasi asan niti ọ̀ran yi; pe gẹgẹ bi mo ti wi, ki ẹnyin ki o le mura tẹlẹ: Bi awọn ninu ará Makedonia ba bá mi wá, ti nwọn si bá nyin li aimura tẹlẹ, ki oju ki o máṣe tì wa (laiwipe ẹnyin,) niti igbẹkẹle yi. Nitorina ni mo ṣe rò pe o yẹ lati gbà awọn arakunrin niyanju, ki nwọn ki o ṣaju tọ̀ nyin wá, ki nwọn ki o si mura ẹ̀bun nyin silẹ, ti ẹ ti ṣe ileri tẹlẹ ki a le ṣe eyi na silẹ, ki o le jasi bi ohun ẹ̀bun, ki o má si ṣe dabi ti ojukòkoro.
Kà II. Kor 9
Feti si II. Kor 9
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Kor 9:1-5
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò