Tobẹ̃ ti awa fi gba Titu niyanju pe, bi o ti bẹ̀rẹ na, bẹ̃ni ki o si pari ẹbun ọfẹ yi ninu nyin pẹlu. Ṣugbọn bi ẹnyin ti pọ̀ li ohun gbogbo, ni igbagbọ́, ati ọ̀rọ, ati ìmọ, ati ninu igbiyanjú gbogbo, ati ni ifẹ nyin si wa, ẹ kiyesi ki ẹnyin ki o pọ̀ ninu ẹbun ọfẹ yi pẹlu. Kì iṣe nipa aṣẹ ni mo fi nsọ, ṣugbọn ki a le ri idi otitọ ifẹ nyin pẹlu, nipa igbiyanjú awọn ẹlomiran. Nitori ẹnyin mọ̀ ore-ọfẹ Oluwa wa Jesu Kristi, pe bi on ti jẹ ọlọrọ̀ rí, ṣugbọn nitori nyin o di talaka, ki a le sọ nyin di ọlọrọ̀ nipa aini rẹ̀.
Kà II. Kor 8
Feti si II. Kor 8
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Kor 8:6-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò