Ẹnyin ara Korinti, a ti bá nyin sọ otitọ ọ̀rọ, ọkàn wa ṣipayá sí nyin. A kò ni nyin lara nitori wa, ṣugbọn a ńni nyin lara nitori ifẹ-ọkàn ẹnyin tikaranyin. Njẹ fun ẹsan iru kanna (emi nsọ bi ẹnipe fun awọn ọmọ mi,) ki ẹnyin di kikún pẹlu. Ẹ máṣe fi aidọgba dàpọ pẹlu awọn alaigbagbọ́: nitori ìdapọ kili ododo ni pẹlu aiṣododo? ìdapọ kini imọlẹ si ni pẹlu òkunkun? Irẹpọ̀ kini Kristi si ni pẹlu Beliali? tabi ipin wo li ẹniti o gbagbọ́ ni pẹlu alaigbàgbọ? Irẹpọ̀ kini tẹmpili Ọlọrun si ni pẹlu oriṣa? nitori ẹnyin ni tẹmpili Ọlọrun alãye; gẹgẹ bi Ọlọrun ti wipe, Emi ó gbé inu wọn, emi o si mã rìn ninu wọn; emi o si jẹ Ọlọrun wọn, nwọn o si jẹ enia mi. Nitorina ẹ jade kuro larin wọn, ki ẹ si yà ara nyin si ọ̀tọ, li Oluwa wi, ki ẹ máṣe fi ọwọ́ kàn ohun aimọ́; emi o si gbà nyin. Emi o si jẹ Baba fun nyin, ẹnyin o si jẹ ọmọkunrin mi ati ọmọbinrin mi, li Oluwa Olodumare wi.
Kà II. Kor 6
Feti si II. Kor 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Kor 6:11-18
10 Days
Many Christians believe the only way to fight sin is to grit our teeth and rise above temptation. But you can’t fight sin with your mind; you must fight it with your heart. Based on the book Rewire Your Heart, this ten-day look at some of the most important verses about your heart will help you discover how to fight sin by allowing the Gospel to rewire your heart.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò