II. Kor 5:2-4

II. Kor 5:2-4 YBCV

Nitori nitõtọ awa nkerora ninu eyi, awa si nfẹ gidigidi lati fi ile wa lati ọrun wá wọ̀ wa: Bi o ba ṣepe a ti wọ̀ wa li aṣọ, a kì yio bá wa ni ìhoho. Nitori awa ti mbẹ ninu agọ́ yi nkerora nitõtọ, ẹrù npa wa: kì iṣe nitori ti awa nfẹ ijẹ alaiwọ̀ṣọ, ṣugbọn ki a le wọ̀ wa li aṣọ, ki iyè ki o le gbé ara kiku mì.