II. Kor 5:19-20

II. Kor 5:19-20 YBCV

Eyini ni pe, Ọlọrun wà nínu Kristi, o mba araiye làja sọdọ ara rẹ̀, kò si kà irekọja wọn si wọn lọrùn; o si ti fi ọ̀rọ ìlaja le wa lọwọ. Nitorina awa ni ikọ̀ fun Kristi, bi ẹnipe Ọlọrun nti ọdọ wa ṣipẹ fun nyin: awa mbẹ̀ nyin nipò Kristi, ẹ ba Ọlọrun làja.