II. Kor 5:14-16

II. Kor 5:14-16 YBCV

Nitori ifẹ Kristi nrọ̀ wa; nitori awa rò bayi, pe bi ẹnikan ba ti kú fun gbogbo enia, njẹ gbogbo wọn li o ti kú: O si ti kú fun gbogbo wọn, pe ki awọn ti o wà lãye ki o má si ṣe wà lãye fun ara wọn mọ́, bikoṣe fun ẹniti o kú nitori wọn, ti o si ti jinde. Nitorina lati isisiyi lọ awa kò mọ̀ ẹnikan nipa ti ara mọ́; bi awa tilẹ ti mọ̀ Kristi nipa ti ara, ṣugbọn nisisiyi awa kò mọ̀ ọ bẹ̃ mọ́.