II. Kor 4:8-11

II. Kor 4:8-11 YBCV

A npọn wa loju niha gbogbo, ṣugbọn ara kò ní wa: a ndãmú wa, ṣugbọn a kò sọ ireti nù. A nṣe inunibini si wa, ṣugbọn a kò kọ̀ wa silẹ; a nrẹ̀ wa silẹ, ṣugbọn a kò si pa wa run; Nigbagbogbo awa nru ikú Jesu Oluwa kiri li ara wa, ki a le fi ìye Jesu hàn pẹlu li ara wa. Nitoripe nigbagbogbo li a nfi awa ti o wà lãyè fun ikú nitori Jesu, ki a le fi ìye Jesu hàn ninu ara kikú wa pẹlu.