II. Kor 4:5-6

II. Kor 4:5-6 YBCV

Nitori awa kò wãsu awa tikarawa, bikoṣe Kristi Jesu Oluwa; awa tikarawa si jẹ ẹrú nyin nitori Jesu. Nitori Ọlọrun, ẹniti o wipe ki imọlẹ ki o mọlẹ lati inu òkunkun jade, on li o ti nmọlẹ li ọkàn wa, lati fun wa ni imọlẹ ìmọ ogo Ọlọrun li oju Jesu Kristi.