II. Kor 3:12-14

II. Kor 3:12-14 YBCV

Njẹ nitorina bi a ti ni irú ireti bi eyi, awa nfi igboiya pupọ sọ̀rọ. Kì si iṣe bi Mose, ẹniti o fi iboju bo oju rẹ̀, ki awọn ọmọ Israeli má ba le tẹjumọ wo opin eyi ti nkọja lọ. Ṣugbọn oju-inu wọn fọ́: nitoripe titi fi di oni oloni ní kika majẹmu lailai, iboju na wà laiká soke; iboju ti a ti mu kuro ninu Kristi.