II. Kor 2:9-11

II. Kor 2:9-11 YBCV

Nitori eyi na pẹlu ni mo ti kọwe, ki emi ki o le mọ̀ ẹri nyin, bi ẹnyin ba ṣe eletí ọmọ li ohun gbogbo. Ṣugbọn ẹniti ẹnyin ba fi ohunkohun jì fun, emi fi jì pẹlu: nitori ohun ti emi pẹlu ba ti fi jì, bi mo ba ti fi ohunkohun jì, nitori tinyin ni mo ti fi ji niwaju Kristi. Ki Satani má bã rẹ́ wa jẹ: nitori awa kò ṣe alaimọ̀ arekereke rẹ̀.