II. Kor 2:12-14

II. Kor 2:12-14 YBCV

Ṣugbọn nigbati mo de Troa lati wãsu ihinrere Kristi, ti ilẹkun si ṣí silẹ fun mi lati ọdọ Oluwa wá, Emi kò ni alafia li ọkàn mi, nitoriti emi ko ri Titu arakunrin mi: ṣugbọn nigbati mo ti dagbere fun wọn, mo rekọja lọ si Makedonia. Ṣugbọn ọpẹ́ ni fun Ọlọrun, ẹniti nyọ̀ ayọ iṣẹgun lori wa nigbagbogbo ninu Kristi, ti o si nfi õrùn ìmọ rẹ̀ hàn nipa wa nibigbogbo.