II. Kor 12:7-8

II. Kor 12:7-8 YBCV

Ati nitori ọ̀pọlọpọ iṣipaya, ki emi ki o má ba gbé ara mi ga rekọja, a si ti fi ẹgún kan si mi lara, iranṣẹ Satani, lati pọn mi loju, ki emi ki o má ba gberaga rekọja. Nitori nkan yi ni mo ṣe bẹ̀ Oluwa nigba mẹta pe, ki o le kuro lara mi.