Ẹnyin ha rò pe ni gbogbo akoko yi àwa nṣe àwíjàre niwaju nyin? awa nsọ̀rọ niwaju Ọlọrun ninu Kristi: ṣugbọn awa nṣe ohun gbogbo, olufẹ ọwọn, lati mu nyin duro. Nitori ẹru mba mi pe, nigbati mo ba de, emi kì yio bá nyin gẹgẹ bi irú eyi ti mo fẹ, ati pe ẹnyin ó si ri mi gẹgẹ bi irú eyi ti ẹnyin kò fẹ: ki ija, owu-jijẹ, ibinu, ipinya, isọrọ-ẹni-lẹhin, ijirọsọ, igberaga, irukerudo, ki o má ba wà: Ati nigbati mo ba si pada de, ki Ọlọrun mi má ba rẹ̀ mi silẹ loju nyin, ati ki emi ki o má bã sọkun nitori ọpọlọpọ awọn ti o ti ṣẹ̀ na, ti nwọn kò si ronupiwada ẹ̀ṣẹ ìwa-ẽri, ati ti àgbere, ati ti wọ̀bia ti nwọn ti dá.
Kà II. Kor 12
Feti si II. Kor 12
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Kor 12:19-21
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò