Tabi ẹ̀ṣẹ ni mo dá ti emi nrẹ̀ ara mi silẹ ki a le gbé nyin ga, nitoriti mo ti wasu ihinrere Ọlọrun fun nyin lọfẹ? Emi ja ijọ miran li ole, mo ngbà owo ki emi ki o le sìn nyin. Nigbati mo si wà pẹlu nyin, ti mo si ṣe alaini, emi kò jẹ́ ẹrù fun ẹnikẹni: nitoriti ohun ti mo ṣe alaini awọn ara ti o ti Makedonia wá fi kún u; ati ninu ohun gbogbo mo ti pa ara mi mọ́ ki emi maṣe jẹ ẹrù fun nyin, bẹ̃li emi ó si mã pa ara mi mọ́. Bi otitọ Kristi ti mbẹ ninu mi, kò sí ẹniti o le da mi lẹkun iṣogo yi ni gbogbo ẹkùn Akaia. Nitori kini? nitori emi kò fẹran nyin ni bi? Ọlọrun mọ̀. Ṣugbọn ohun ti mo nṣe li emi ó si mã ṣe, ki emi ki o le mu igberaga kuro lọwọ awọn ti gberaga pe ninu ohun ti nwọn nṣogo, ki a le ri wọn gẹgẹ bi awa. Nitori irú awọn enia bẹ̃ li awọn eke Aposteli, awọn ẹniti nṣiṣẹ ẹ̀tan, ti npa ara wọn dà di Aposteli Kristi. Kì si iṣe ohun iyanu; nitori Satani tikararẹ̀ npa ara rẹ̀ dà di angẹli imọlẹ. Nitorina kì iṣe ohun nla bi awọn iranṣẹ rẹ̀ pẹlu ba pa ara wọn dà bi awọn iranṣẹ ododo; igbẹhin awọn ẹniti yio ri gẹgẹ bi iṣẹ wọn.
Kà II. Kor 11
Feti si II. Kor 11
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Kor 11:7-15
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò