II. Kor 11:4-6

II. Kor 11:4-6 YBCV

Nitori bi ẹniti mbọ̀ wá ba nwãsu Jesu miran, ti awa kò ti wasu rí, tabi bi ẹnyin ba gbà ẹmí miran, ti ẹnyin kò ti gbà ri, tabi ihinrere miran, ti ẹnyin kò ti tẹwọgbà, ẹnyin iba ṣe rere lati fi ara da a. Nitori mo ṣiro rẹ pe emi kò rẹ̀hin li ohunkohun si awọn Aposteli gigagiga na. Ṣugbọn bi mo tilẹ jẹ òpe li ọ̀rọ, ki iṣe ni ìmọ; ṣugbọn awa ti fihan dajudaju fun nyin lãrin gbogbo enia.