Ni ìrin àjò nigbakugba, ninu ewu omi, ninu ewu awọn ọlọṣa, ninu ewu awọn ara ilu mi, ninu ewu awọn keferi, ninu ewu ni ilu, ninu ewu li aginjù, ninu ewu loju okun, ninu ewu larin awọn eke arakunrin; Ninu lãlã ati irora, ninu iṣọra nigbakugba, ninu ebi ati orùngbẹ, ninu àwẹ nigbakugba, ninu otutù ati ìhoho. Pẹlu nkan wọnni ti o wà lode, eyi ti nwọjọ tì mi li ojojumọ́, emi ko yé ṣe aniyan gbogbo ijọ. Tani iṣe alailera, ti emi kò ṣe alailera? tabi tali a mu kọsẹ̀, ti ara mi kò gbina? Bi emi kò le ṣaima ṣogo, emi o kuku mã ṣogo nipa awọn nkan ti iṣe ti ailera mi. Ọlọrun ati Baba Oluwa wa Jesu Kristi, ẹniti iṣe olubukún julọ lailai, mọ̀ pe emi kò ṣeke.
Kà II. Kor 11
Feti si II. Kor 11
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Kor 11:26-31
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò