II. Kor 11:24-27

II. Kor 11:24-27 YBCV

Nigba marun ni mo gbà paṣan ogoji dín kan lọwọ awọn Ju. Nigba mẹta li a fi ọgọ lù mi, ẹkanṣoṣo li a sọ mi li okuta, ẹ̃mẹta li ọkọ̀ rì mi, ọsán kan ati oru kan ni mo wà ninu ibú. Ni ìrin àjò nigbakugba, ninu ewu omi, ninu ewu awọn ọlọṣa, ninu ewu awọn ara ilu mi, ninu ewu awọn keferi, ninu ewu ni ilu, ninu ewu li aginjù, ninu ewu loju okun, ninu ewu larin awọn eke arakunrin; Ninu lãlã ati irora, ninu iṣọra nigbakugba, ninu ebi ati orùngbẹ, ninu àwẹ nigbakugba, ninu otutù ati ìhoho.