Mo si tún wipe, Ki ẹnikẹni ki o máṣe rò pe aṣiwère ni mi; ṣugbọn bi bẹ̃ ba ni, ẹ gbà mi bi aṣiwere, ki emi ki o le gbé ara mi ga diẹ. Ohun ti emi nsọ, emi kò sọ ọ nipa ti Oluwa, ṣugbọn bi aṣiwèrè ninu igbẹkẹle iṣogo yi. Ọpọlọpọ li o sa nṣogo nipa ti ara, emi ó ṣogo pẹlu. Nitori ẹnyin fi inu didùn gbà awọn aṣiwère, nigbati ẹnyin tikaranyin jẹ ọlọ́gbọn. Nitori ẹnyin farada a bi ẹnikan ba sọ nyin di ondè, bi ẹnikan ba jẹ nyin run, bi ẹnikan ba gbà lọwọ nyin, bi ẹnikan ba gbé ara rẹ̀ ga, bi ẹnikan ba gbá nyin loju. Emi nwi lọna ẹ̀gan, bi ẹnipe awa jẹ alailera. Ṣugbọn ninu ohunkohun ti ẹnikan ni igboiya (emi nsọrọ were), emi ni igboiya pẹlu. Heberu ni nwọn bi? bẹ̃li emi. Israeli ni nwọn bi? bẹ̃li emi. Irú ọmọ Abrahamu ni nwọn bi? bẹ̃li emi. Iranṣẹ Kristi ni nwọn bi? (emi nsọ bi aṣiwère) mo ta wọn yọ; niti lãlã lọpọlọpọ, niti paṣan mo rekọja, niti tubu nigbakugba, niti ikú nigbapupọ.
Kà II. Kor 11
Feti si II. Kor 11
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Kor 11:16-23
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò