II. Kor 11:12-15

II. Kor 11:12-15 YBCV

Ṣugbọn ohun ti mo nṣe li emi ó si mã ṣe, ki emi ki o le mu igberaga kuro lọwọ awọn ti gberaga pe ninu ohun ti nwọn nṣogo, ki a le ri wọn gẹgẹ bi awa. Nitori irú awọn enia bẹ̃ li awọn eke Aposteli, awọn ẹniti nṣiṣẹ ẹ̀tan, ti npa ara wọn dà di Aposteli Kristi. Kì si iṣe ohun iyanu; nitori Satani tikararẹ̀ npa ara rẹ̀ dà di angẹli imọlẹ. Nitorina kì iṣe ohun nla bi awọn iranṣẹ rẹ̀ pẹlu ba pa ara wọn dà bi awọn iranṣẹ ododo; igbẹhin awọn ẹniti yio ri gẹgẹ bi iṣẹ wọn.