Awa si ti mura tan lati gbẹsan gbogbo aigbọran, nigbati igbọran nyin ba pé. Ẹnyin si nwò nkan gẹgẹ bi nwọn ti fi ara hàn lode. Bi ẹnikẹni ba gbẹkẹle ara rẹ̀ pe, ti Kristi li on iṣe, ẹ jẹ ki on ki o si tún rò eyi ninu ara rẹ̀ pe, bi on ti jẹ́ ti Kristi, gẹgẹ bẹ̃li awa pẹlu si jẹ́ ti Kristi. Nitori bi mo tilẹ nṣogo aṣerekọja nitori aṣẹ wa, ti Oluwa ti fifun wa fun idagbasoke nyin ki iṣe fun ìbiṣubu nyin, oju ki yio tì mi; Ki o máṣe dabi ẹnipe emi o fi iwe-kikọ dẹruba nyin. Nitori nwọn wipe, iwe rẹ̀ wuwo, nwọn si lagbara; ṣugbọn ìrísi rẹ̀ jẹ alailera, ọ̀rọ rẹ̀ kò nilari. Ki irú enia bẹ̃ ki o ro bayi pe, irú ẹniti awa iṣe li ọ̀rọ nipa iwe-kikọ nigbati awa kò si, irú bẹ̃li awa o si jẹ ni iṣe pẹlu nigbati awa ba wà.
Kà II. Kor 10
Feti si II. Kor 10
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Kor 10:6-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò