II. Kor 1:8-12

II. Kor 1:8-12 YBCV

Ará, awa kò sá fẹ ki ẹnyin ki o wà li aimọ̀ nipa wahalà wa, ti o dé bá wa ni Asia, niti pe a pọ́n wa loju gidigidi rekọja agbara wa, tobẹ̃ ti ireti kò tilẹ si fun ẹmi wa mọ́: Ṣugbọn awa ni idahùn ikú ninu ara wa, ki awa ki o máṣe gbẹkẹle ara wa, bikoṣe Ọlọrun ti njí okú dide: Ẹniti o ti gbà wa kuro ninu ikú ti o tobi tobẹ̃, ti o si ngbà wa: ẹniti awa gbẹkẹ wa le pe yio si mã gbà wa sibẹsibẹ; Ẹnyin pẹlu nfi adura nyin ṣe iranlọwọ fun wa, pe nitori ẹ̀bun ti a fifun wa lati ọwọ ọ̀pọlọpọ enia, ki ọ̀pọlọpọ ki o le mã dupẹ nitori wa. Nitori eyi ni iṣogo wa, ẹ̀rí-ọkàn wa, pe, ni iwa-mimọ́ ati ododo Ọlọrun, kì iṣe nipa ọgbọ́n ara, bikoṣe nipa ore-ọfẹ Ọlọrun, li awa nhuwa li aiye, ati si nyin li ọ̀pọlọpọ.