II. Kor 1:7-10

II. Kor 1:7-10 YBCV

Ati ireti wa nipa tiyin duro ṣinṣin, awa si mọ̀ pe, bi ẹnyin ti jẹ alabapin ninu ìya, bẹ̃li ẹnyin jẹ ninu itunu na pẹlu. Ará, awa kò sá fẹ ki ẹnyin ki o wà li aimọ̀ nipa wahalà wa, ti o dé bá wa ni Asia, niti pe a pọ́n wa loju gidigidi rekọja agbara wa, tobẹ̃ ti ireti kò tilẹ si fun ẹmi wa mọ́: Ṣugbọn awa ni idahùn ikú ninu ara wa, ki awa ki o máṣe gbẹkẹle ara wa, bikoṣe Ọlọrun ti njí okú dide: Ẹniti o ti gbà wa kuro ninu ikú ti o tobi tobẹ̃, ti o si ngbà wa: ẹniti awa gbẹkẹ wa le pe yio si mã gbà wa sibẹsibẹ

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú II. Kor 1:7-10